Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 6:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá yín, nítorí ẹ kò sí lábẹ́ Òfin; abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni ẹ wà.

15. Kí ló wá kù kí á ṣe? Ṣé kí á máa dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé a kò sí lábẹ́ òfin, abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni a wà. Ká má rí i.

16. Ẹ kò mọ̀ pé ẹrú ẹni tí ẹ bá ń gbọ́ràn sí lẹ́nu lẹ jẹ́, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fara yín ṣẹrú fún, tí ẹ sì ń jíṣẹ́ fún? Ẹ lè fi ara yín ṣẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó fikú san án fun yín; ẹ sì lè fìgbọràn ṣọ̀gá fún ara yín, kí ó sì fun yín ní ìdáláre.

17. Ọpẹ́ ni fỌlọrun, nítorí pé ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ti wá ń fi tọkàntọkàn gba irú ẹ̀kọ́ tí a gbé kalẹ̀ níwájú yín.

18. A ti tu yín sílẹ̀ ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ti di ẹrú iṣẹ́ rere.

19. Mò ń fọ èdè tí ó lè yé eniyan, nítorí ọgbọ́n yín kò ì tíì kọjá ohun tí a lè fi ojú rí. Bí ẹ ti gbé ara yín fún ìwà èérí ati ìwà tinú-mi-ni-n-óo-ṣe, tí a sì fi yín sílẹ̀ kí ẹ máa ṣe bí ó ti wù yín, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ wá fi ara yín jìn fún iṣẹ́ rere, kí ẹ sìn ín fún iṣẹ́ mímọ́.

20. Nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, kò sí ohun tí ẹ bá iṣẹ́ rere dàpọ̀.

21. Èrè wo ni ẹ rí gbà lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àfi ohun tí ń tì yín lójú nisinsinyii? Ikú ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí.

22. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí.

23. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.

Ka pipe ipin Romu 6