orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 16 BIBELI MIMỌ (BM)

Paulu Kí Ọpọlọpọ Eniyan ninu Ìjọ Romu

1. Mo fẹ́ kí ẹ gba Febe bí arabinrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkiria.

2. Ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ní orúkọ Kristi gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ onigbagbọ. Kí ẹ ràn án lọ́wọ́ ní ọ̀nàkọ́nà tí ó bá fẹ́; nítorí ó jẹ́ ẹni tí ó ran ọpọlọpọ eniyan ati èmi pàápàá lọ́wọ́.

3. Ẹ kí Pirisila ati Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi Jesu.

4. Wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti gbà mí lọ́wọ́ ikú. Èmi nìkan kọ́ ni mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, gbogbo ìjọ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu náà dúpẹ́ pẹlu.

5. Ẹ kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn náà.Ẹ kí Epenetu àyànfẹ́ mi, ẹni tí ó jẹ́ onigbagbọ kinni ní ilẹ̀ Esia.

6. Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ láàrin yín.

7. Ẹ kí Andironiku ati Junia, àwọn ìbátan mi tí a jọ wà lẹ́wọ̀n. Olókìkí ni wọ́n láàrin àwọn òjíṣẹ́ Kristi, wọ́n sì ti di onigbagbọ ṣiwaju mi.

8. Ẹ kí Ampiliatu àyànfẹ́ mi ninu Oluwa.

9. Ẹ kí Ubanu alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi ati Sitaku àyànfẹ́ mi.

10. Ẹ kí Apele, akikanju onigbagbọ. Ẹ kí àwọn ará ilé Arisitobulu.

11. Ẹ kí Hẹrodioni ìbátan mi. Ẹ kí àwọn ará ilé Nakisu tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ.

12. Ẹ kí Tirufina ati Tirufosa, àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ Oluwa. Ẹ kí Pasisi, arabinrin àyànfẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ pupọ ninu Oluwa.

13. Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà.

14. Ẹ kí Asinkiritu, Filegọnta, Herime, Patiroba, Herima ati àwọn arakunrin tí ó wá pẹlu wọn.

15. Ẹ kí Filologu ati Julia, Nerea ati arabinrin rẹ̀, ati Olimpa ati gbogbo àwọn onigbagbọ tí ó wà lọ́dọ̀ wọn.

16. Ẹ rọ̀ mọ́ ara yín, kí ẹ sì kí ara yín pẹlu alaafia. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín.

Paulu Ṣe Ìkìlọ̀

17. Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ máa fura sí àwọn tí ó ń dá ìyapa sílẹ̀ ati àwọn tí ń múni ṣìnà, tí wọn ń ṣe àwọn nǹkan tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ yẹra fún irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀.

18. Nítorí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe iranṣẹ Oluwa wa Kristi, ikùn ara wọn ni wọ́n ń bọ. Wọn a máa fi ọ̀rọ̀ dídùn ati kí á máa pọ́n eniyan tan àwọn tí kò bá fura jẹ.

19. Ìròyìn ti tàn ká ibi gbogbo pé ẹ dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Èyí mú inú mi dùn nítorí yín. Mo fẹ́ kí ẹ jẹ́ amòye ninu nǹkan rere, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ òpè ní ti àwọn nǹkan burúkú.

20. Kí Ọlọrun orísun alaafia mu yín ṣẹgun Satani ní kíákíá. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.

Àwọn Tí Ó Wà lọ́dọ̀ Paulu Kí Ìjọ Romu

21. Timoti alábàáṣiṣẹ́ mi ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Lukiusi ati Jasoni ati Sosipata, àwọn ìbátan wa.

22. Èmi Tatiu tí mò ń bá Paulu kọ ìwé yìí ki yín: Ẹ kú iṣẹ́ Oluwa.

23. Gaiyu náà ki yín. Òun ni ó gbà mí lálejò bí ó ti gba gbogbo ìjọ lálejò. Erastu, akápò ìlú, ki yín. Kuatu arakunrin wa náà ki yín.[

24. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.]

Oore-ọ̀fẹ́

25. Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ati iwaasu nípa Jesu Kristi ti wí ati gẹ́gẹ́ bí àdììtú tí Ọlọrun dì láti ayérayé, ṣugbọn tí ó wá tú

26. ní àkókò yìí. Ìwé àwọn wolii ni ó ṣe ìṣípayá ohun tí ó fara pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọrun ayérayé, pé kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́, kí wọ́n mọ̀, kí wọ́n sì gbà.

27. Ògo ni fún Ọlọrun ọlọ́gbọ́n kanṣoṣo nípa Jesu Kristi títí laelae. Amin.