Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 12:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín.

2. Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé.

3. Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un.

Ka pipe ipin Romu 12