Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 11:18-33 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró.

19. Ìwọ yóo wá wí pé, “Gígé ni a gé àwọn ẹ̀ka kúrò kí á lè fi mí rọ́pò wọn.”

20. Lóòótọ́ ni. A gé wọn kúrò nítorí wọn kò gbàgbọ́, nípa igbagbọ ni ìwọ náà fi wà ní ipò rẹ. Mú èrò ìgbéraga kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì ní ọkàn ìbẹ̀rù.

21. Nítorí bí Ọlọrun kò bá dá àwọn tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí, kò ní dá ìwọ náà sí.

22. Nítorí náà ṣe akiyesi ìyọ́nú Ọlọrun ati ìrorò rẹ̀. Ó rorò sí àwọn tí ó kùnà. Yóo yọ́nú sí ọ, tí o bá farabalẹ̀ gba ìyọ́nú rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo gé ìwọ náà kúrò pẹlu.

23. Àwọn Juu tí a gé kúrò yóo tún bọ́ sí ipò wọn pada, bí wọn bá kọ ọ̀nà aigbagbọ sílẹ̀. Ọlọrun lágbára láti tún lọ́ wọn pada sí ibi tí ó ti gé wọn.

24. Ìwọ tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi olifi tí ó la ilẹ̀ hù ninu ìgbẹ́, tí a lọ́ mọ́ ara igi olifi inú oko, tí ẹ̀dá wọn yàtọ̀ sí ara wọn, báwo ni yóo ti rọrùn tó láti tún lọ́ àwọn tí ó jẹ́ ara igi olifi inú oko tẹ́lẹ̀ mọ́ ara igi tí a ti gé wọn kúrò!

25. Ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ ohun àṣírí yìí, kí ẹ má baà ro ara yín jù bí ó ti yẹ lọ. Òun ni pé, apá kan ninu àwọn ọmọ Israẹli yóo jẹ́ alágídí ọkàn títí di ìgbà tí iye àwọn tí a yàn láti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo fi dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

26. Lẹ́yìn náà, a óo wá gba gbogbo Israẹli là. A ti kọ ọ́ sílẹ̀ pé,“Olùdáǹdè yóo wá láti Sioni,yóo mú gbogbo ìwàkiwà kúrò ní ilé Jakọbu.

27. Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dá,lẹ́yìn tí mo bá mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”

28. Nítorí pé àwọn Juu kọ ìyìn rere, wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọrun, èyí sì ṣe yín láǹfààní. Ṣugbọn níwọ̀n ìgbà tí Ọlọrun ti yàn wọ́n nítorí àwọn baba-ńlá orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ sibẹ.

29. Nítorí Ọlọrun kò jẹ́ kábàámọ̀ pé òun fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn kí ó wá gbà á pada.

30. Bí ẹ̀yin fúnra yín ti jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọrun nígbà kan rí, ṣugbọn tí ó wá ṣàánú yín nígbà tí àwọn Juu ṣàìgbọràn,

31. bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nisinsinyii tí ẹ̀yin náà rí àánú gbà, wọ́n di aláìgbọràn, kí àwọn náà lè rí àánú Ọlọrun gbà.

32. Nítorí Ọlọrun ti ka gbogbo eniyan sí ẹlẹ́bi nítorí àìgbọràn wọn, kí ó lè ṣàánú fún gbogbo wọn papọ̀.

33. Ọlà ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun mà kúkú jinlẹ̀ pupọ o! Àwámárìídìí ni ìdájọ́ rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ tayọ ohun tí ẹ̀dá lè tú wò.

Ka pipe ipin Romu 11