Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 11:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ǹjẹ́, mo bèèrè: ṣé Ọlọrun ti wá kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ ni? Rárá o! Ọmọ Israẹli ni èmi fúnra mi. Ìran Abrahamu ni mí, láti inú ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹnjamini.

2. Ọlọrun kò kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tí ó ti yàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Tabi ẹ kò mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ninu ìtàn Elija? Ó ní,

3. “Oluwa, wọ́n ti pa àwọn wolii rẹ, wọ́n ti wó pẹpẹ ìrúbọ rẹ, èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá mi láti pa.”

4. Ṣugbọn kí ni Ọlọrun wí fún un? Ó ní “Ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan ṣì kù fún mi tí wọn kò tíì wólẹ̀ bọ Baali rí.”

5. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní àkókò yìí, àwọn kan kù tí Ọlọrun yàn nítorí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.

6. Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́.

7. Kí wá ni? Ohun tí Israẹli ń wá kò tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Ṣugbọn ó tẹ àwọn díẹ̀ tí a yàn ninu wọn lọ́wọ́. Etí àwọn yòókù di sí ìpè Ọlọrun,

Ka pipe ipin Romu 11