Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 10:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí Kristi ti fi òpin sí Òfin láti mú gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ rí ìdáláre níwájú Ọlọrun.

5. Mose kọ sílẹ̀ báyìí nípa ìdáláre tí Òfin lè fúnni pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa wọ́n mọ́, yóo ti ipa wọn rí ìyè.”

6. Ṣugbọn báyìí ni Ìwé Mímọ́ wí nípa ìdáláre tí à ń gbà nípa igbagbọ, pé, “Má ṣe wí ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóo gòkè lọ sọ́run?’ ” (Èyí ni láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀.)

7. “Tabi, ‘Ta ni yóo wọ inú ọ̀gbun ilẹ̀ lọ?’ ” (Èyí ni, láti mú Kristi jáde kúrò láàrin àwọn òkú.)

8. Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé:

9. bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là.

10. Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà.

11. Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.”

Ka pipe ipin Romu 10