Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Kinni 3:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.

10. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú,tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára,ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánupẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ,kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

11. Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú,kí ó máa hu ìwà rere.Ó níláti máa wá alaafia,kí ó sì máa lépa rẹ̀.

12. Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo,ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn.Ṣugbọn ojú Oluwa kan síàwọn tí ó ń ṣe burúkú.”

13. Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere?

14. Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú.

15. Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní.

16. Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

17. Nítorí ó sàn fun yín tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kí ẹ jìyà, nítorí pé ẹ̀ ń ṣe rere, jù pé ẹ̀ ń ṣe ibi lọ.

18. Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.

Ka pipe ipin Peteru Kinni 3