Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Kinni 1:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nítorí náà, ẹ ṣe ọkàn yìn gírí. Ẹ máa ṣe pẹ̀lẹ́. Ẹ máa retí oore-ọ̀fẹ́ tí yóo jẹ́ tiyín nígbà tí Jesu Kristi bá tún dé.

14. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ń gbọ́ràn, ẹ má gbé irú ìgbé-ayé yín ti àtijọ́, nígbà tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín tí ẹ kò mọ̀ pé àìdára ni.

15. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pè yín ti jẹ́ mímọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ́ mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín.

16. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, Ọlọrun ní, “Ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí èmi náà jẹ́ mímọ́.”

17. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń pe Ọlọrun ní Baba tí kì í ṣe ojuṣaaju, tí ó jẹ́ pé bí iṣẹ́ olukuluku bá ti rí ní ó fi ń ṣe ìdájọ́, ẹ máa fi ìbẹ̀rù gbé ìgbé-ayé yín ní ìwọ̀nba àkókò tí ẹ ní.

18. Nítorí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí ó lè bàjẹ́, bíi fadaka ati wúrà, ni a fi rà yín pada kúrò ninu ìgbé-ayé asán tí ẹ jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.

19. Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n.

20. Kí á tó dá ayé ni a ti yan Kristi fún iṣẹ́ yìí. Ṣugbọn ní àkókò ìkẹyìn yìí ni ó tó fi ara hàn nítorí tiyín.

21. Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun.

22. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín.

23. A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí.

24. Nítorí,“Gbogbo ẹlẹ́ran-ara dàbí Koríko,gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó.Koríko a máa gbẹ,òdòdó a máa rẹ̀,

25. ṣugbọn ọ̀rọ̀ Oluwa yóo wà títí lae.”Òun ni ọ̀rọ̀ tí à ń waasu rẹ̀ fun yín.

Ka pipe ipin Peteru Kinni 1