Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Keji 3:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò.

11. Nígbà tí ìparun ń bọ̀ wá bá gbogbo nǹkan báyìí, irú ìgbé-ayé wo ni ó yẹ kí ẹ máa gbé? Ẹ níláti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ ati olùfọkànsìn,

12. kí ẹ máa retí ọjọ́ Ọlọrun, kí ẹ máa ṣe akitiyan pé kí ó tètè dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parun, gbogbo ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo yọ́ ninu iná.

13. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, à ń dúró de àwọn ọ̀run titun ati ayé titun níbi tí òdodo yóo máa wà.

14. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun.

15. Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un.

16. Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù.

17. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí.

18. Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin.

Ka pipe ipin Peteru Keji 3