Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 3:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àtẹ ìfẹ́kà rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Yóo gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tótó. Yóo kó ọkà rẹ̀ jọ sinu abà, ṣugbọn sísun ni yóo sun fùlùfúlù ninu iná àjóòkú.”

13. Nígbà náà ni Jesu lọ láti ilẹ̀ Galili, sọ́dọ̀ Johanu ní odò Jọdani, kí Johanu lè ṣe ìrìbọmi fún un.

14. Ṣugbọn Johanu fẹ́ kọ̀ fún un, ó ní, “Èmi gan-an ni mo nílò pé kí o ṣe ìrìbọmi fún mi; ìwọ ni ó tún tọ̀ mí wá?”

15. Jesu dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí á ṣe é bẹ́ẹ̀ ná, nítorí báyìí ni ó yẹ fún wa bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ láṣepé.” Nígbà náà ni Johanu gbà fún un.

16. Bí Jesu ti ṣe ìrìbọmi tán, tí ó gòkè jáde kúrò ninu omi, ọ̀run pínyà lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá rí Ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, tí ó ń bà lé e.

17. Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i gidigidi.”

Ka pipe ipin Matiu 3