Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:8-23 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí.

9. Báyìí ni ohun tí wolii Jeremaya, wí ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Wọ́n mú ọgbọ̀n owó fadaka náà, iye tí a dá lé orí ẹ̀mí náà, nítorí iye tí àwọn ọmọ Israẹli ń dá lé eniyan lórí nìyí,

10. wọ́n lo owó náà fún ilẹ̀ amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti pàṣẹ fún mi.”

11. Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?”Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”

12. Ṣugbọn bí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti ń fi ẹ̀sùn kàn án tó, kò fèsì rárá.

13. Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “O kò gbọ́ irú ẹ̀sùn tí wọn ń fi kàn ọ́ ni?”

14. Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn gbolohun kan ṣoṣo, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gomina pupọ.

15. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkókò àjọ̀dún, gomina a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn eniyan, ẹnikẹ́ni tí wọn bá fẹ́.

16. Ní àkókó náà, ẹlẹ́wọ̀n olókìkí kan wà tí ó ń jẹ́ Jesu Baraba.

17. Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?”

18. Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun.

19. Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.”

20. Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu.

21. Gomina bi wọ́n pé, “Ta ni ninu àwọn meji yìí ni ẹ fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fun yín?”Wọ́n sọ pé, “Baraba ni.”

22. Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?”Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”

23. Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?”Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”

Ka pipe ipin Matiu 27