Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:55-66 BIBELI MIMỌ (BM)

55. Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un.

56. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.

57. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.

58. Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un.

59. Nígbà tí Josẹfu ti gba òkú náà, ó fi aṣọ funfun tí ó mọ́ wé e.

60. Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀.

61. Maria Magidaleni ati Maria keji wà níbẹ̀, wọ́n jókòó ní iwájú ibojì náà.

62. Ní ọjọ́ keji, ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ̀dún, àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ Pilatu.

63. Wọ́n ní, “Alàgbà, a ranti pé ẹlẹ́tàn nì sọ nígbà tí ó wà láàyè pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹta òun óo jí dìde.

64. Nítorí náà, pàṣẹ kí wọ́n ṣọ́ ibojì náà títí di ọjọ́ kẹta. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lè wá jí òkú rẹ̀ lọ, wọn yóo wá wí fún àwọn eniyan pé, ‘Ó ti jinde kúrò ninu òkú.’ Ìtànjẹ ẹẹkeji yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”

65. Pilatu bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí ẹ ní olùṣọ́. Ẹ lọ fi wọ́n ṣọ́ ibojì náà bí ó ti tọ́ lójú yín.”

66. Wọ́n bá lọ, wọ́n sé ẹnu ibojì náà, wọ́n fi èdìdì sí ara òkúta tí wọ́n gbé dí i. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sibẹ pẹlu.

Ka pipe ipin Matiu 27