Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:53-63 BIBELI MIMỌ (BM)

53. Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn.

54. Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”

55. Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un.

56. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.

57. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.

58. Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un.

59. Nígbà tí Josẹfu ti gba òkú náà, ó fi aṣọ funfun tí ó mọ́ wé e.

60. Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀.

61. Maria Magidaleni ati Maria keji wà níbẹ̀, wọ́n jókòó ní iwájú ibojì náà.

62. Ní ọjọ́ keji, ọjọ́ tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ̀dún, àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ Pilatu.

63. Wọ́n ní, “Alàgbà, a ranti pé ẹlẹ́tàn nì sọ nígbà tí ó wà láàyè pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹta òun óo jí dìde.

Ka pipe ipin Matiu 27