Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:46-60 BIBELI MIMỌ (BM)

46. Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

47. Nígbà tí àwọn kan tí ó dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń pe Elija.”

48. Lẹsẹkẹsẹ ọ̀kan ninu wọn sáré, ó ti nǹkankan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi sórí ọ̀pá láti fi fún un mu.

49. Ṣugbọn àwọn yòókù ń sọ pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí a wò bí Elija yóo wá gbà á là.”

50. Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́.

51. Aṣọ ìkélé tí ó wà ninu Tẹmpili ya sí meji láti òkè dé ilẹ̀. Ilẹ̀ mì tìtì. Àwọn òkè sán.

52. Òkúta ẹnu ibojì ṣí, a sì jí ọ̀pọ̀ òkú àwọn olódodo dìde.

53. Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn.

54. Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”

55. Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un.

56. Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.

57. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.

58. Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un.

59. Nígbà tí Josẹfu ti gba òkú náà, ó fi aṣọ funfun tí ó mọ́ wé e.

60. Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀.

Ka pipe ipin Matiu 27