Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 27:18-31 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun.

19. Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.”

20. Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu.

21. Gomina bi wọ́n pé, “Ta ni ninu àwọn meji yìí ni ẹ fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fun yín?”Wọ́n sọ pé, “Baraba ni.”

22. Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?”Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”

23. Pilatu bi wọ́n pé, “Ohun burúkú wo ni ó ṣe?”Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”

24. Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.”

25. Gbogbo àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí àwa ati àwọn ọmọ wa!”

26. Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu.

27. Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí.

28. Wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n wá fi aṣọ àlàárì bò ó lára.

29. Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.”

30. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń tutọ́ sí i lára. Wọ́n mú ọ̀pá, wọ́n ń kán an mọ́ ọn lórí.

31. Nígbà tí wọn ti fi ṣe ẹlẹ́yà tẹ́rùn, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n fi tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Wọ́n bá mú un lọ láti kàn án mọ́ agbelebu.

Ka pipe ipin Matiu 27