Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 26:69-75 BIBELI MIMỌ (BM)

69. Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.”

70. Ṣugbọn Peteru sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní, “N kò mọ ohun tí ò ń sọ.”

71. Bí ó ti ń lọ sí ẹnu ọ̀nà, iranṣẹbinrin mìíràn tún rí i, ó bá sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”

72. Peteru tún sẹ́, ó búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.”

73. Ó ṣe díẹ̀ si, àwọn tí ó dúró níbẹ̀ tọ Peteru lọ, wọ́n sọ fún un pé, “Òtítọ́ ni pé ọ̀kan ninu wọn ni ìwọ náà í ṣe nítorí ọ̀rọ̀ rẹ fihàn bẹ́ẹ̀!”

74. Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó tún ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin náà.”Lẹsẹkẹsẹ àkùkọ kọ.

75. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ, pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ó bá bọ́ sóde, ó sọkún gidigidi.

Ka pipe ipin Matiu 26