Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 24:22-35 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Bí Ọlọrun kò bá dín àwọn ọjọ́ náà kù ni, ẹ̀dá kankan kì bá tí là. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́, Ọlọrun yóo dín àwọn ọjọ́ náà kù.

23. “Ní àkókò náà, bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, ‘Wò ó! Mesaya náà nìyí níhìn-ín!’ Tabi ‘Wò ó! Mesaya ló wà lọ́hùn-ún nì!’ ẹ má ṣe gbàgbọ́.

24. Nítorí àwọn Mesaya èké ati àwọn wolii èké yóo dìde. Wọn yóo fi àmì ńlá hàn, wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ; bí ó bá ṣeéṣe fún wọn, wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.

25. Ẹ wò ó, ogun àsọtẹ́lẹ̀ nìyí.

26. “Nítorí náà, bí wọn bá sọ fun yín pé, ‘Ẹ wá wò ó ní aṣálẹ̀,’ ẹ má lọ. Tabi tí wọ́n bá sọ pé, ‘Ẹ wá wò ó ní ìyẹ̀wù,’ ẹ má ṣe gbàgbọ́.

27. Nítorí bí mànàmáná ti ń kọ ní ìlà oòrùn, tí ó sì ń mọ́lẹ̀ dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ gan-an ni dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí.

28. “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn gúnnugún yóo péjọ sí.

29. “Lẹsẹkẹsẹ lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ láti ọ̀run. Gbogbo àwọn agbára tí ó wà ní ọ̀run ni a óo mì jìgìjìgì.

30. Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá.

31. Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji.

32. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí.

33. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọnyi, kí ẹ̀yin náà mọ̀ pé àkókò súnmọ́ tòsí, ó ti dé ẹnu ọ̀nà.

34. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn eniyan ìran yìí kò ní tíì kú tán títí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀.

35. Ọ̀run ati ayé yóo kọjá lọ ṣugbọn ọ̀rọ̀ mi kò ní kọjá lọ.

Ka pipe ipin Matiu 24