Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 21:41-46 BIBELI MIMỌ (BM)

41. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.”

42. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé,‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pataki ní igun ilé.Iṣẹ́ Oluwa ni èyí,ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’

43. “Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [

44. Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”]

45. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí.

46. Wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí àwọn eniyan gbà á bíi wolii.

Ka pipe ipin Matiu 21