Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 21:36-45 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn.

37. Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’

38. Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’

39. Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.

40. “Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?”

41. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.”

42. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé,‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pataki ní igun ilé.Iṣẹ́ Oluwa ni èyí,ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’

43. “Nítorí èyí mo sọ fun yín pé a gba ìjọba Ọlọrun lọ́wọ́ yín, a fi fún orílẹ̀-èdè tí yóo so èso tí ó yẹ. [

44. Bí eniyan bá kọlu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo rún wómúwómú. Bí òkúta yìí bá bọ́ lu eniyan, yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”]

45. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí.

Ka pipe ipin Matiu 21