Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 21:32-41 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.”

33. Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀.

34. Nígbà tí ó tó àkókò ìkórè, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ sí àwọn alágbàro náà láti gba ìpín tirẹ̀ wá ninu èso rẹ̀.

35. Ṣugbọn àwọn alágbàro náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n na àwọn kan, wọ́n pa àwọn kan, wọ́n sọ àwọn mìíràn ní òkúta.

36. Sibẹ ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn tí wọ́n pọ̀ ju àwọn ti àkọ́kọ́ lọ; ṣugbọn bákan náà ni àwọn alágbàro yìí ṣe sí wọn.

37. Ní ìgbẹ̀yìn ó wá rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó ní, ‘Wọn óo bu ọlá fún ọmọ mi.’

38. Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro náà rí ọmọ rẹ̀, wọ́n wí láàrin ara wọn pé, ‘Àrólé rẹ̀ ni èyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’

39. Wọ́n bá mú un, wọ́n tì í jáde kúrò ninu ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.

40. “Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóo ṣe sí àwọn alágbàro náà?”

41. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Pípa ni yóo pa àwọn olubi náà, yóo fi ọgbà àjàrà rẹ̀ lé àwọn alágbàro mìíràn lọ́wọ́, tí yóo fún un ní èso ní àkókò tí ó wọ̀.”

Ka pipe ipin Matiu 21