Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 21:13-26 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó sọ fún wọn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura ni ilé mi jẹ́,’ ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí.”

14. Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ninu Tẹmpili, ó sì wò wọ́n sàn.

15. Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin rí àwọn ohun ìyanu tí Jesu ṣe, tí wọ́n tún gbọ́ bí àwọn ọmọde ti ń kígbe ninu Tẹmpili pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi,” inú wọn ru.

16. Wọ́n sọ fún un pé, “O kò gbọ́ ohun tí àwọn wọnyi ń wí ni?”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́. Ẹ kò tíì kà á pé, ‘Lẹ́nu àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ni ìwọ ti gba ìyìn pípé?’ ”

17. Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì jáde kúrò lọ sí Bẹtani. Níbẹ̀ ni ó gbé sùn.

18. Lówùúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ó ti ń pada lọ sinu ìlú, ebi ń pa á.

19. Bí ó ti rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́nà, ó yà lọ sí ìdí rẹ̀, ṣugbọn, kò rí nǹkankan lórí rẹ̀ àfi kìkì ewé. Ó bá sọ fún un pé, “O kò ní so mọ́ laelae.” Lẹsẹkẹsẹ ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà bá gbẹ!

20. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ń sọ pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ lẹsẹkẹsẹ.”

21. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.

22. Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ninu adura, bí ẹ bá gbàgbọ́, ẹ óo rí i gbà.”

23. Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?”

24. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, èmi náà yóo wá sọ irú agbára tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi.

25. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, báwo ló ti jẹ́: ṣé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?”Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn, wọ́n ń wí pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’

26. Bí a bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ a bẹ̀rù àwọn eniyan, nítorí gbogbo eniyan gbà pé wolii tòótọ́ ni Johanu.”

Ka pipe ipin Matiu 21