Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 17:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu arakunrin Jakọbu, wọ́n lọ sí orí òkè gíga kan; àwọn nìkan wà níbẹ̀.

2. Jesu bá para dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ wá ń tàn bí oòrùn. Aṣọ rẹ̀ mọ́ gbòò bí ọjọ́.

3. Wọ́n wá rí Mose ati Elija tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀.

4. Peteru bá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, kì bá dára kí á máa gbé ìhín. Bí o bá fẹ́, èmi yóo pa àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.”

5. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”

6. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, wọ́n dojúbolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n pupọ.

7. Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó ní, “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.”

8. Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnikẹ́ni mọ́, àfi Jesu nìkan.

9. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.”

10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í pé, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́kọ́ dé?”

11. Ó dá wọn lóhùn pé, “Òtítọ́ ni pé Elija yóo wá, yóo sì mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.

12. Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.”

Ka pipe ipin Matiu 17