Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 16:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn.

2. Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’

3. Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí.

4. Ìran burúkú ati oníbọkúbọ ń wá àmì; ṣugbọn a kò ní fi àmì kan fún un, àfi àmì Jona.”Ó bá fi wọ́n sílẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ.

5. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rékọjá sí òdìkejì òkun, wọ́n gbàgbé láti mú oúnjẹ lọ́wọ́.

6. Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati àwọn Sadusi.”

7. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wí láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ wá ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”

8. Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń sọ láàrin ara yín nípa oúnjẹ tí ẹ kò ní, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré?

9. Òye kò ì tíì ye yín sibẹ? Ẹ kò ranti burẹdi marun-un tí mo fi bọ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan ati iye agbọ̀n àjẹkù tí ẹ kó jọ?

10. Ti burẹdi meje ńkọ́, tí mo fi bọ́ ẹgbaaji (4,000) eniyan ati iye apẹ̀rẹ̀ àjẹkù tí ẹ kó jọ?

11. Kí ló dé tí kò fi ye yín pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni mò ń sọ? Ẹ ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati Sadusi.”

12. Nígbà náà ni ó wá yé wọn pé kì í ṣe ti ìwúkàrà tí à ń fi sinu burẹdi ni ó ń sọ, ti ẹ̀kọ́ àwọn Farisi ati Sadusi ni ó ń sọ.

Ka pipe ipin Matiu 16