Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 15:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sọ fún un pé, “Lé obinrin yìí lọ, nítorí ó ń pariwo tẹ̀lé wa lẹ́yìn.”

24. Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.”

25. Ṣugbọn obinrin náà wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ràn mí lọ́wọ́.”

26. Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!”

27. Obinrin náà ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa. Ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti inú àwo oúnjẹ oluwa wọn.”

28. Nígbà náà ni Jesu sọ fún un pé, “Obinrin yìí! Igbagbọ rẹ tóbi gidi. Kí ó rí fún ọ bí o ti fẹ́.” Ara ọdọmọbinrin rẹ̀ bá dá láti àkókò náà.

29. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀.

30. Ọ̀pọ̀ eniyan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n gbé àwọn arọ wá, ati àwọn afọ́jú, àwọn amúkùn-ún ati àwọn odi, ati ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bá wò wọ́n sàn.

31. Ẹnu ya àwọn eniyan, nígbà tí wọ́n rí i tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn amúkùn-ún di alára líle, tí àwọn arọ ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran. Wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun Israẹli.

32. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ ó ní, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi; wọn kò ní oúnjẹ mọ́. N kò fẹ́ tú wọn ká pẹlu ebi ninu, kí òòyì má baà gbé wọn lọ́nà.”

33. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Níbo ni a óo ti rí oúnjẹ ní aṣálẹ̀ yìí tí yóo yó àwọn eniyan tí ó pọ̀ tó báyìí?”

Ka pipe ipin Matiu 15