Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 13:42-56 BIBELI MIMỌ (BM)

42. Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.

43. Àwọn olódodo yóo wá máa ràn bí oòrùn ninu ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

44. “Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ìṣúra iyebíye kan tí wọ́n fi pamọ́ ninu ilẹ̀. Nígbà tí ẹnìkan rí i, ó bò ó mọ́lẹ̀, ó lọ tayọ̀tayọ̀, ó ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá ra ilẹ̀ náà.

45. “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ọkunrin oníṣòwò kan tí ó ń wá ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye kan.

46. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó dára pupọ, ó lọ ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá rà á.

47. “Báyìí tún ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí àwọ̀n tí a dà sinu òkun, tí ó kó oríṣìíríṣìí ẹja.

48. Nígbà tí ó kún, wọ́n fà á lọ sí èbúté, wọ́n jókòó, wọ́n ṣa àwọn ẹja tí ó dára jọ sinu garawa, wọ́n sì da àwọn tí kò wúlò nù.

49. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóo wá, wọn óo yanjú àwọn eniyan burúkú kúrò láàrin àwọn olódodo,

50. wọn yóo jù wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.”

51. Jesu bi wọ́n pé, “Ṣé gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ye yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”

52. Ó wá sọ fún wọn pé, “Nítorí èyí ni amòfin tí ó bá ti kọ́ nípa ìjọba ọ̀run ṣe dàbí baálé ilé kan, tí ó ń mú nǹkan titun ati nǹkan àtijọ́ jáde láti inú àpò ìṣúra rẹ̀.”

53. Lẹ́yìn tí Jesu ti parí gbogbo àwọn òwe wọnyi, ó kúrò níbẹ̀.

54. Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí?

55. Àbí ọmọ gbẹ́nà-gbẹ́nà yẹn kọ́ ni? Tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Maria, tí àwọn arakunrin rẹ̀ ń jẹ́ Jakọbu ati Josẹfu ati Simoni ati Judasi?

56. Gbogbo àwọn arabinrin rẹ̀ kọ́ ni wọ́n wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín? Níbo ni ó wá ti rí gbogbo nǹkan wọnyi?”

Ka pipe ipin Matiu 13