Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 10:33-41 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

34. “Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá.

35. Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀.

36. Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.

37. “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.

38. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi.

39. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀.

40. “Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.

41. Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yóo gba èrè tí ó yẹ wolii. Ẹni tí ó bá gba olódodo ní orúkọ olódodo yóo gba èrè olódodo.

Ka pipe ipin Matiu 10