Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 10:30-38 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Gbogbo irun orí yín ni ó níye.

31. Nítorí náà ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ.

32. “Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

33. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Baba mi tí ń bẹ lọ́run.

34. “Ẹ má rò pé mo mú alaafia wá sáyé. N kò mú alaafia wá; idà ni mo mú wá.

35. Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀.

36. Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.

37. “Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.

38. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi.

Ka pipe ipin Matiu 10