Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 10:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ!

16. “Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.

17. Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn eniyan, nítorí wọn yóo fà yín lọ siwaju ìgbìmọ̀ láti fẹ̀sùn kàn yín; wọn yóo nà yín ninu àwọn ilé ìpàdé wọn.

18. Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.

19. Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà.

20. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni yóo máa sọ̀rọ̀, ẹ̀mí Baba yín ni yóo máa sọ̀rọ̀ ninu yín.

21. “Arakunrin yóo fi arakunrin rẹ̀ fún ikú pa; baba yóo fi ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóo gbógun ti àwọn òbí wọn, wọn yóo fi wọ́n fún ikú pa.

22. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá fara dà á títí dé òpin, òun ni a óo gbà là.

23. Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé.

24. “Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju oluwa rẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Matiu 10