Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 1:18-25 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Bí ìtàn ìbí Jesu Kristi ti rí nìyí. Nígbà tí Maria ìyá rẹ̀ wà ní iyawo àfẹ́sọ́nà Josẹfu, kí wọn tó ṣe igbeyawo, a rí i pé Maria ti lóyún láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

19. Eniyan rere ni Josẹfu ọkọ rẹ̀, kò fẹ́ dójú tì í, ó fẹ́ rọra kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́.

20. Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní.

21. Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii nì lè ṣẹ pé,

23. “Wundia kan yóo lóyún, yóo bí ọmọkunrin kan; wọn yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.” (Ìtumọ̀, “Imanuẹli” ni “Ọlọrun wà pẹlu wa.”)

24. Nígbà tí Josẹfu jí láti ojú oorun, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Oluwa náà ti pàṣẹ fún un. Ó mú iyawo rẹ̀ sọ́dọ̀.

25. Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu.

Ka pipe ipin Matiu 1