6. Ẹ̀rù tí ó bà wọ́n pupọ kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ì bá wí.
7. Ìkùukùu kan bá ṣíji bò wọ́n, ohùn kan bá wá láti inú ìkùukùu náà tí ó wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
8. Lójijì, bí wọ́n ti wò yíká, wọn kò rí ẹnìkankan lọ́dọ̀ wọn mọ́, àfi Jesu nìkan.
9. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, Jesu pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ròyìn ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí òun, Ọmọ-Eniyan, yóo fi jí dìde kúrò ninu òkú.
10. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, wọ́n ń bá ara wọn jiyàn nípa ìtumọ̀ jíjí dìde kúrò ninu òkú.
11. Wọ́n bá bi í léèrè pé, “Kí ló dé tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́ dé?”
12. Ó dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Elija ni ó níláti kọ́ dé láti mú ohun gbogbo bọ̀ sípò.” Ó wá bi wọ́n pé, “Báwo ni a ti ṣe kọ nípa Ọmọ-Eniyan pé ó níláti jìyà pupọ, kí a sì fi àbùkù kàn án?”
13. Ó sì tún wí fún wọn pé, “Elija ti dé, wọ́n ti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ nípa rẹ̀.”
14. Nígbà tí Jesu dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí ọpọlọpọ eniyan pẹlu àwọn amòfin, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn.
15. Lẹsẹkẹsẹ bí gbogbo àwọn eniyan ti rí i, ẹnu yà wọ́n, wọ́n bá sáré lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń kí i.
16. Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀yin ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ń jiyàn lé lórí?”
17. Ẹnìkan ninu wọn bá dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, ọmọ mi tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di odi ni mo mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.
18. Níbikíbi tí ó bá ti dé sí i, ẹ̀mí èṣù yìí á gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà yóo máa yọ ìfòòfó lẹ́nu, yóo wa eyín pọ̀, ara rẹ̀ yóo wá le gbandi. Mo sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pé kí wọn lé ẹ̀mí náà jáde, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é.”