Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 9:34-41 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Wọ́n bá dákẹ́ nítorí ní ọ̀nà, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn lórí ta ni ó ṣe pataki jùlọ.

35. Lẹ́yìn tí ó ti jókòó, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ọ̀gá, ó níláti ṣe iranṣẹ fún gbogbo eniyan.”

36. Ó bá fa ọmọde kan dìde ní ààrin wọn, ó gbé e sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

37. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan ninu àwọn ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, kì í ṣe èmi ni ó gbà, ṣugbọn ó gba ẹni tí ó rán mi wá sí ayé.”

38. Johanu wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a rí ẹnìkan tí ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ṣugbọn a gbìyànjú láti dá a lẹ́kun, nítorí kì í ṣe ara wa.”

39. Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Ẹ má ṣe dá a lẹ́kun, nítorí kò sí ẹni tí yóo fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóo yára sọ ọ̀rọ̀ ibi nípa mi.

40. Nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí wa, tiwa ni.

41. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fun yín ní omi mu nítorí tèmi, nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kristi, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo rí èrè rẹ̀ gbà.

Ka pipe ipin Maku 9