Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 8:8-9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

8-9. Àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó ẹ̀rúnrún àjẹkù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ ńlá meje. Àwọn eniyan tí wọn jẹun tó bí ẹgbaaji (4,000). Lẹ́yìn náà Jesu ní kí wọn túká.

10. Lẹsẹkẹsẹ ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá lọ sí agbègbè Dalimanuta.

11. Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n.

12. Inú rẹ̀ bàjẹ́, ó ní, “Nítorí kí ni àwọn eniyan ṣe ń wá àmì lóde òní? Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé a kò ní fún wọn ní àmì kan.”

13. Ó bá fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó lọ sí òdìkejì òkun.

14. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbé láti mú burẹdi lọ́wọ́ àfi ọ̀kan ṣoṣo tí wọn ní ninu ọkọ̀ ojú omi.

15. Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.”

16. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò ní burẹdi ni.”

17. Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀?

18. Ẹ ní ojú lásán ni, ẹ kò ríran? Ẹ ní etí lásán ni, ẹ kò fi gbọ́ràn?

19. Ẹ kò ranti nígbà tí mo bu burẹdi marun-un fún ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan, agbọ̀n mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Mejila.”

20. Ó tún bi wọ́n pé, “Nígbà tí mo fi burẹdi meje bọ́ àwọn ẹgbaaji (4,000) eniyan, agbọ̀n ńlá mélòó ni àjẹkù tí ẹ kó jọ?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Meje.”

Ka pipe ipin Maku 8