Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 6:37-55 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.”Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!”

38. Ó bi wọ́n pé, “Ìba oúnjẹ wo ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó.”Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n ní “Burẹdi marun-un ni ati ẹja meji.”

39. Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko.

40. Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta.

41. Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn.

42. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó.

43. Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila.

44. Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000).

45. Lẹsẹkẹsẹ ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọn ṣiwaju rẹ̀ lọ sí òdìkejì òkun ní agbègbè Bẹtisaida. Lẹ́yìn náà ó ní kí àwọn eniyan túká.

46. Nígbà tí ó ti dágbére fún wọn, ó lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura.

47. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ninu ọkọ̀ ní ààrin òkun, òun nìkan ni ó kù lórí ilẹ̀.

48. Ó rí i pé pẹlu ipá ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Ó tó bí agogo mẹta òru kí Jesu tó máa lọ sọ́dọ̀ wọn. Ó ń rìn lórí omi, ó fẹ́ kọjá lára wọn.

49. Nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn lórí omi, wọ́n ṣebí iwin ni, wọ́n bá kígbe.

50. Nítorí gbogbo wọn ni wọ́n rí i tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.Ṣugbọn lójú kan náà ó fọhùn sí wọn, ó ní, “Ẹ fi ọkàn balẹ̀. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

51. Ó bá wọ inú ọkọ̀ tọ̀ wọ́n lọ, afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ẹnu yà wọ́n lọpọlọpọ,

52. nítorí pé iṣẹ́ ìyanu ti burẹdi kò yé wọn, nítorí òpè ni wọ́n.

53. Nígbà tí wọ́n la òkun já, wọ́n dé Genesarẹti, wọ́n bá gúnlẹ̀.

54. Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, lẹsẹkẹsẹ àwọn eniyan mọ̀ wọ́n.

55. Wọ́n bá ń súré láti gbogbo àdúgbò ibẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wọn lórí ibùsùn wá sí ibikíbi tí wọn bá gbọ́ pé Jesu wà.

Ka pipe ipin Maku 6