Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 6:35-49 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n wí fún un pé, “Aṣálẹ̀ nìhín yìí, ilẹ̀ sì ń ṣú lọ.

36. Jẹ́ kí àwọn eniyan túká, kí wọn lè lọ sí àwọn abà ati abúlé tí ó wà yíká láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”

37. Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.”Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!”

38. Ó bi wọ́n pé, “Ìba oúnjẹ wo ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó.”Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n ní “Burẹdi marun-un ni ati ẹja meji.”

39. Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko.

40. Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta.

41. Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn.

42. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó.

43. Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila.

44. Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000).

45. Lẹsẹkẹsẹ ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọn ṣiwaju rẹ̀ lọ sí òdìkejì òkun ní agbègbè Bẹtisaida. Lẹ́yìn náà ó ní kí àwọn eniyan túká.

46. Nígbà tí ó ti dágbére fún wọn, ó lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura.

47. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ninu ọkọ̀ ní ààrin òkun, òun nìkan ni ó kù lórí ilẹ̀.

48. Ó rí i pé pẹlu ipá ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Ó tó bí agogo mẹta òru kí Jesu tó máa lọ sọ́dọ̀ wọn. Ó ń rìn lórí omi, ó fẹ́ kọjá lára wọn.

49. Nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn lórí omi, wọ́n ṣebí iwin ni, wọ́n bá kígbe.

Ka pipe ipin Maku 6