Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 3:5-19 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò.

6. Lẹsẹkẹsẹ àwọn Farisi jáde lọ láti gbìmọ̀ pọ̀ pẹlu àwọn alátìlẹ́yìn Hẹrọdu lórí ọ̀nà tí wọn yóo gbà pa á.

7. Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra lọ sí ẹ̀bá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan sì ń tẹ̀lé e. Wọ́n wá láti Galili ati Judia ati Jerusalẹmu;

8. láti Idumea ati apá ìlà oòrùn odò Jọdani ati agbègbè Tire ati ti Sidoni. Ogunlọ́gọ̀ eniyan wọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó ń ṣe.

9. Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn tọ́jú ọkọ̀ ojú omi kan sí ìtòsí nítorí àwọn eniyan, kí wọn má baà fún un pa.

10. Nítorí ó wo ọpọlọpọ sàn tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn aláìsàn ń ti ara wọn, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án.

11. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù bá rí i, wọ́n a wolẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n a máa kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.”

12. Kíkìlọ̀ ni ó máa ń kìlọ̀ fún wọn gan-an kí wọn má ṣe fi òun hàn.

13. Lẹ́yìn náà, ó wá gun orí òkè lọ, ó pe àwọn tí ó wù ú sọ́dọ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ.

14. Ó bá yan àwọn mejila, ó pè wọ́n ní aposteli, kí wọn lè wà pẹlu rẹ̀, kí ó lè máa rán wọn lọ waasu,

15. kí wọn lè ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

16. Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru,

17. ati Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu àbúrò rẹ̀, ó sọ wọ́n ní Boanage, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Àwọn ọmọ ààrá”;

18. ati Anderu, Filipi, Batolomiu, Matiu, ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Tadiu, ati Simoni, ọmọ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ Kenaani,

19. ati Judasi Iskariotu ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Ka pipe ipin Maku 3