Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 2:19-28 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ iyawo wà lọ́dọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn, wọ́n kò lè máa gbààwẹ̀.

20. Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí a óo gba ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn óo gbààwẹ̀ nígbà náà.

21. “Kò sí ẹni tíí fi ìrépé asọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, aṣọ titun náà yóo súnkì lára ẹ̀wù náà, yóo wá tún fà á ya ju ti àkọ́kọ́ lọ.

22. Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí náà yóo bẹ́ àpò náà, ati ọtí ati àpò yóo bá ṣòfò. Ṣugbọn inú àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí.”

23. Ní àkókò kan ní Ọjọ́ Ìsinmi, bí Jesu ti ń la ààrin oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà jẹ bí wọn tí ń lọ lọ́nà.

24. Àwọn Farisi wí fún un pé, “Wò bí wọn ti ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi!”

25. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí kò ní oúnjẹ, tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?

26. Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ ní àkókò Abiatari Olórí Alufaa, tí ó jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí kò yẹ kí ẹnikẹ́ni jẹ, àfi alufaa nìkan, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ jẹ?”

27. Ó wá wí fún wọn pé, “Lílò eniyan ni a dá Ọjọ́ Ìsinmi fún, a kò dá eniyan fún Ọjọ́ Ìsinmi.

28. Nítorí náà, Ọmọ-Eniyan ni Oluwa ohun gbogbo ati ti Ọjọ́ Ìsinmi pẹlu.”

Ka pipe ipin Maku 2