45. Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé, Judasi lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó kí i, ó ní, “Olùkọ́ni!” Ó sì da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.
46. Àwọn tí ó bá a wá bá ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.
47. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn tí ó dúró fa idà yọ, ó fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa, ó bá gé e létí.
48. Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ẹ mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́ láti wá mú mi bí ẹni pé ẹ̀ ń bọ̀ wá mú ọlọ́ṣà?
49. Lojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili tí mò ń kọ́ àwọn eniyan, ẹ kò ṣe mú mi nígbà náà. Ṣugbọn kí àkọsílẹ̀ lè ṣẹ ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.”
50. Nígbà náà ni Gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá fi í sílẹ̀, wọ́n bá sálọ.
51. Ọdọmọkunrin kan tí ó jẹ́ pé aṣọ funfun nìkan ni ó dà bo ara ń tẹ̀lé e. Nígbà tí wọ́n gbá a mú,
52. ó fi aṣọ ìbora rẹ̀ sílẹ̀, ó bá sálọ níhòòhò.
53. Wọ́n mú Jesu lọ sí ọ̀dọ̀ Olórí Alufaa, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ati àwọn amòfin wá péjọ sibẹ.
54. Peteru wà ní òkèèrè, ó ń tẹ̀lé e títí ó fi wọ agbo-ilé Olórí Alufaa, ó bá jókòó pẹlu àwọn iranṣẹ, wọ́n jọ ń yá iná.
55. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo Ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí tí ó lòdì sí Jesu, kí wọ́n baà lè pa á, ṣugbọn wọn kò rí.
56. Nítorí ọpọlọpọ ní ń jẹ́rìí èké sí i, ṣugbọn ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu.
57. Àwọn kan wá dìde, wọ́n ń jẹ́rìí èké sí i pé,
58. “A gbọ́ nígbà tí ó ń wí pé, ‘Èmi yóo wó Tẹmpili tí eniyan kọ́ yìí, láàrin ọjọ́ mẹta, èmi óo gbé òmíràn dìde tí eniyan kò kọ́.’ ”
59. Sibẹ ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu.