Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 13:7-22 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé.

8. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo gbé ogun ti orílẹ̀-èdè, ìjọba yóo dìde sí ìjọba, ilẹ̀ yóo mì tìtì ní oríṣìíríṣìí ìlú, ìyàn yóo mú ní ọpọlọpọ ilẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora nìwọ̀nyí.

9. “Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn.

10. Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná.

11. Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

12. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yóo ṣe ikú pa ara wọn; bẹ́ẹ̀ ni baba yóo ṣe sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóo tàpá sí àwọn òbí wọn, wọn yóo sì pa wọ́n.

13. Gbogbo eniyan ni yóo kórìíra yín nítorí orúkọ mi. Ṣugbọn ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun ni a óo gbàlà.

14. “Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ– (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)– nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè.

15. Nígbà tí ẹni tí ó wà ní òkè ilé bá sọ̀kalẹ̀, kí ó má ṣe wọ ilé lọ láti mú ohunkohun jáde.

16. Kí alágbàro ní oko má ṣe dúró mú ẹ̀wù rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀.

17. Ọjọ́ ìṣòro ni ọjọ́ náà yóo jẹ́ fún àwọn aboyún ati àwọn tí ó ń fún ọmọ lọ́mú ní àkókò náà.

18. Kí ẹ gbadura kí ó má jẹ́ àkókò tí òtútù mú pupọ.

19. Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae.

20. Bí kò bá jẹ́ pé Oluwa dín àkókò náà kù, ẹ̀dá kankan kì bá tí kù láàyè. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́ tí Ọlọrun yàn, ó dín àkókò rẹ̀ kù.

21. “Bí ẹnikẹ́ni bá wí fun yín pé. ‘Wo Kristi níhìn-ín,’ tabi ‘Wò ó lọ́hùn-ún,’ ẹ má gbàgbọ́.

22. Nítorí àwọn Kristi èké ati àwọn wolii èké yóo dìde, wọn yóo máa ṣe iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ. Wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ, bí ó bá ṣeéṣe.

Ka pipe ipin Maku 13