Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 13:5-11 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ni Jesu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàn yín jẹ.

6. Ọpọlọpọ yóo wá ní orúkọ mi tí wọ́n yóo wí pé àwọn ni Kristi. Wọn yóo tan ọpọlọpọ jẹ.

7. Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa oríṣìíríṣìí ogun nítòsí ati ní ọ̀nà jíjìn, ẹ má ṣe dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ó níláti rí, ṣugbọn òpin ayé kò tíì dé.

8. Nítorí orílẹ̀-èdè yóo gbé ogun ti orílẹ̀-èdè, ìjọba yóo dìde sí ìjọba, ilẹ̀ yóo mì tìtì ní oríṣìíríṣìí ìlú, ìyàn yóo mú ní ọpọlọpọ ilẹ̀. Ìbẹ̀rẹ̀ ìrora nìwọ̀nyí.

9. “Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn.

10. Ṣugbọn a níláti kọ́kọ́ waasu ìyìn rere fún orílẹ̀-èdè gbogbo ná.

11. Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

Ka pipe ipin Maku 13