Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 13:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí ó ti ń jáde kúrò ninu Tẹmpili, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olùkọ́ni, wo òkúta wọnyi ati ilé yìí, wò ó bí wọn ti tóbi tó!”

2. Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.”

3. Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé,

4. “Sọ fún wa, nígbà wo ni àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣẹ ati pé kí ni àmì tí yóo hàn kí gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tó rí bẹ́ẹ̀?”

Ka pipe ipin Maku 13