Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Maku 1:35-43 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan.

36. Simoni ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ń wá a kiri.

37. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n wí fún un pé, “Gbogbo eniyan ní ń wá ọ.”

38. Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí àwọn abúlé mìíràn tí ó wà ní ìtòsí kí n lè waasu níbẹ̀, nítorí ohun tí mo wá sí ayé fún ni èyí.”

39. Ó bá lọ, ó ń waasu ninu àwọn ilé ìpàdé wọn ní gbogbo ilẹ̀ Galili, ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.

40. Ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”

41. Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.”

42. Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀, ara rẹ̀ sì dá.

43. Jesu fi ohùn líle kìlọ̀ fún un, lẹsẹkẹsẹ ó bá ní kí ó máa lọ.

Ka pipe ipin Maku 1