Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 8:32-42 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ lórí òkè. Àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí àwọn kó sí inú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà. Ó bá gbà fún wọn.

33. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi.

34. Nígbà tí àwọn tí ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ ròyìn ní ìlú ati ní ìgbèríko.

35. Àwọn eniyan bà jáde láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀, tí ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, ojú rẹ̀ sì wálẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan.

36. Àwọn tí ó mọ̀ bí ara ọkunrin náà ti ṣe dá ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn.

37. Gbogbo àwọn eniyan agbègbè Geraseni bá bẹ Jesu pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Ó bá tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó pada sí ibi tí ó ti wá.

38. Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀.Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní,

39. “Pada lọ sí ilé rẹ, kí o lọ ròyìn ohun tí Ọlọrun ṣe fún ọ.”Ni ọkunrin náà bá ń káàkiri gbogbo ìlú, ó ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un.

40. Nígbà tí Jesu pada dé, àwọn eniyan fi tayọ̀tayọ̀ gbà á, nítorí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.

41. Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé,

42. nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila.Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.

Ka pipe ipin Luku 8