Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 8:26-34 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Wọ́n gúnlẹ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Geraseni tí ó wà ní òdì keji òkun tí ó dojú kọ ilẹ̀ Galili.

27. Bí ó ti bọ́ sí èbúté, ọkunrin kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù jáde láti inú ìlú wá pàdé rẹ̀. Ó ti pẹ́ tí ó ti fi aṣọ kanra gbẹ̀yìn, kò sì lè gbé inú ilé mọ́, àfi ní itẹ́ òkú.

28. Nígbà tí ó rí Jesu, ó kígbe, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó kébòòsí pé, “Kí ni ó pa èmi ati ìwọ pọ̀, Jesu, ọmọ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo? Mo bẹ̀ ọ́ má dá mi lóró!”

29. Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò ninu ọkunrin yìí. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ní í máa ń dé sí i. Wọn á fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́, wọn á tún kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Ṣugbọn jíjá ni yóo já ohun tí wọ́n fi dè é, ni yóo bá sálọ sinu aṣálẹ̀.

30. Jesu bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”Ó ní, “Ẹgbaagbeje,” Nítorí àwọn ẹ̀mí èṣù tí ó ti wọ inú rẹ̀ pọ̀.

31. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá bẹ Jesu pé kí ó má lé àwọn lọ sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.

32. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ lórí òkè. Àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jẹ́ kí àwọn kó sí inú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà. Ó bá gbà fún wọn.

33. Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá jáde kúrò ninu ọkunrin tí à ń wí yìí, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, ni agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí inú òkun, wọ́n bá rì sómi.

34. Nígbà tí àwọn tí ń tọ́jú agbo ẹlẹ́dẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n bá sá kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ ròyìn ní ìlú ati ní ìgbèríko.

Ka pipe ipin Luku 8