Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 8:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn èyí, Jesu ń rìn káàkiri láti ìlú dé ìlú, ati láti abúlé dé abúlé. Ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ń bá a kiri.

2. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obinrin kan tí Jesu ti wòsàn kúrò ninu ẹ̀mí èṣù ati àìlera ń bá a kiri. Ninu wọn ni Maria tí à ń pè ní Magidaleni wà, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje jáde ninu rẹ̀,

3. ati Joana iyawo Kusa, ọmọ-ọ̀dọ̀ Hẹrọdu, ati Susana ati ọpọlọpọ àwọn mìíràn. Àwọn yìí ni wọ́n ń fi ohun ìní wọn bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ bùkátà wọn.

4. Ọpọlọpọ eniyan ń wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn láti ìlú dé ìlú. Ó wá fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé:

5. “Afunrugbin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ̀ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.

6. Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí àpáta. Nígbà tí ó hù, ó bá gbẹ nítorí kò sí omi.

7. Irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin ẹ̀gún. Nígbà tí òun ati ẹ̀gún jọ dàgbà, ń ṣe ni ẹ̀gún fún un pa.

8. Irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ dáradára, ó dàgbà, ó sì so èso. Irúgbìn kọ̀ọ̀kan so ọgọọgọrun-un.”Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó wá tún sọ pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”

9. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí.

10. Ó ní, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ àṣírí ìjọba Ọlọrun, ṣugbọn fún àwọn yòókù, bí òwe bí òwe ni, pé wọn yóo máa wo nǹkan ṣugbọn wọn kò ní mọ ohun tí wọn rí, wọn yóo máa gbọ́ràn ṣugbọn òye ohun tí wọn gbọ́ kò ní yé wọn.

11. “Ìtumọ̀ òwe yìí nìyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

12. Àwọn tí ó bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà ni àwọn tí wọ́n gbọ́, lẹ́yìn náà èṣù wá, ó mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má baà gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.

13. Àwọn tí ó bọ́ sórí òkúta ni àwọn tí ó gbọ́, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbàgbọ́ fún àkókò díẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ìdánwò dé, wọ́n bọ́hùn.

14. Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́, ṣugbọn àkólékàn ayé, ìlépa ọrọ̀, ati ìgbádùn ayé fún ọ̀rọ̀ náà pa, wọn kò lè dàgbà láti so èso.

15. Àwọn ti ilẹ̀ dáradára ni àwọn tí ó fi ọkàn rere ati ọkàn mímọ́ gba ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso nípa ìfaradà.

16. “Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ tan fìtílà tán, kí ó fi àwo bò ó mọ́lẹ̀, tabi kí ó gbé e sábẹ́ ibùsùn. Orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n ń gbé e kà, kí gbogbo ẹni tí ó bá ń wọlé lè ríran.

17. “Nítorí kò sí ohun kan tí ó pamọ́ tí kò ní fara hàn, kò sì sí nǹkan bòńkẹ́lẹ́ kan tí eniyan kò ní mọ̀.

Ka pipe ipin Luku 8