Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 7:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ.

2. Ọ̀gágun kan ní ẹrú kan tí ó ṣàìsàn, ó fẹ́rẹ̀ kú. Ẹrú náà ṣe ọ̀wọ́n fún un.

3. Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn.

4. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún,

5. nítorí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, òun fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ ilé ìpàdé fún wa.”

6. Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀.

7. Òun ni kò jẹ́ kí èmi fúnra mi wá sọ́dọ̀ rẹ. Ṣugbọn sọ gbolohun kan, ara ọmọ-ọ̀dọ̀ mi yóo sì dá.

8. Nítorí èmi náà jẹ́ ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ. Mo ní àwọn ọmọ-ogun lábẹ́ mi. Bí mo bá sọ fún ọ̀kan pé, ‘Lọ!’ Yóo lọ ni. Bí mo bá sì sọ fún òmíràn pé, ‘Wá!’ Yóo wá ni. Bí mo bá sọ fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ Yóo ṣe é ni.”

9. Nígbà tí Jesu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹnu yà á. Ó bá yipada sí àwọn eniyan tí ó ń tẹ̀lé e, ó ní, “Mò ń sọ fun yín, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!”

10. Nígbà tí àwọn tí ọ̀gágun rán pada dé ilé, wọ́n rí ẹrú náà tí ara rẹ̀ ti dá.

Ka pipe ipin Luku 7