Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 6:32-45 BIBELI MIMỌ (BM)

32. “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn.

33. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

34. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

35. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú.

36. Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.

37. “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín.

38. Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.”

39. Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn.

40. Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Ṣugbọn bí ọmọ-ẹ̀yìn bá jáfáfá yóo dàbí olùkọ́ rẹ̀.

41. “Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi ńlá tí ó wà lójú ìwọ alára?

42. Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.

43. “Igi rere kò lè so èso burúkú. Bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lé so èso rere.

44. Èso tí igi kan bá so ni a óo fi mọ̀ ọ́n. Nítorí eniyan kò lè ká èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹlẹ́gùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò lè rí èso ọsàn lórí igi ọdán.

45. Eniyan rere ń mú ohun rere wá láti inú orísun rere ọkàn rẹ̀. Eniyan burúkú ń mú nǹkan burúkú jáde láti inú ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí ohun tí ó bá wà ninu ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni ń sọ jáde.

Ka pipe ipin Luku 6