Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 6:17-29 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun.

18. Wọ́n wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati pé kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìsàn wọn. Ó tún ń wo àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú sàn.

19. Gbogbo àwọn eniyan ni ó ń wá a, kí wọ́n lè fi ọwọ́ kàn án nítorí agbára ń ti ara rẹ̀ jáde. Ó bá wo gbogbo wọn sàn.

20. Ó bá gbé ojú sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé,“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin talaka,nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọrun.

21. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ebi ń pa nisinsinyii,nítorí ẹ óo yó.Ayọ̀ ń bẹ fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sunkún nisinsinyii,nítorí ẹ óo rẹ́rìn-ín.

22. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín nígbà tí àwọn eniyan bá kórìíra yín, tí wọ́n bá le yín ní ìlú bí arúfin, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n bá fi orúkọ yín pe ibi, nítorí Ọmọ-Eniyan.

23. Ẹ máa yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ sì máa jó, nítorí èrè pọ̀ fun yín ní ọ̀run. Irú nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wolii.

24. “Ṣugbọn ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ gbé,nítorí ẹ ti jẹ ìgbádùn tiyín tán!

25. Ẹ̀yin tí ẹ yó nisinsinyii, ẹ gbé,nítorí ebi ń bọ̀ wá pa yín.Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń yọ̀ nisinsinyii, ẹ gbé,nítorí ọ̀fọ̀ óo ṣẹ̀ yín, ẹ óo sì sunkún.

26. “Nígbà tí gbogbo eniyan bá ń ròyìn yín ní rere, ẹ gbé, nítorí bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wolii.

27. “Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín.

28. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín.

29. Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Luku 6