Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 3:20-35 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Hẹrọdu wá tún fi ti Johanu tí ó sọ sẹ́wọ̀n kún gbogbo ìwà burúkú rẹ̀.

21. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀.

22. Ẹ̀mí Mímọ́ fò wálẹ̀ bí àdàbà ó bà lé e lórí. Ohùn kan wá fọ̀ láti ọ̀run pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi; inú mi dùn sí ọ gidigidi.”

23. Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli,

24. ọmọ Matati, ọmọ Lefi, ọmọ Meliki, ọmọ Janai, ọmọ Josẹfu,

25. ọmọ Matatiya, ọmọ Amosi, ọmọ Nahumu, ọmọ Esili, ọmọ Nagai,

26. ọmọ Maati, ọmọ Matatiya, ọmọ Semehin, ọmọ Joseki, ọmọ Joda,

27. ọmọ Johana, ọmọ Resa, ọmọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ọmọ Neri,

28. ọmọ Meliki, ọmọ Adi, ọmọ Kosamu, ọmọ Elimadamu, ọmọ Eri,

29. ọmọ Joṣua ọmọ Elieseri, ọmọ Jorimu, ọmọ Matati, ọmọ Lefi,

30. ọmọ Simeoni, ọmọ Juda, ọmọ Josẹfu, ọmọ Jonamu, ọmọ Eliakimu,

31. ọmọ Melea, ọmọ Mena, ọmọ Matati, ọmọ Natani, ọmọ Dafidi,

32. ọmọ Jese, ọmọ Obedi, ọmọ Boasi, ọmọ Salimoni, ọmọ Naṣoni,

33. ọmọ Aminadabu, ọmọ Adimini, ọmọ Arini, ọmọ Hesironi, ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda,

34. ọmọ Jakọbu, ọmọ Isaaki, ọmọ Abrahamu, ọmọ Tẹra, ọmọ Nahori,

35. ọmọ Serugi, ọmọ Reu, ọmọ Pelegi, ọmọ Eberi, ọmọ Sela,

Ka pipe ipin Luku 3