Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 24:21-37 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Òun ní àwa ti ń retí pé yóo fún Israẹli ní òmìnira. Ati pé ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọjọ́ kẹta nìyí tí gbogbo rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.

22. Ṣugbọn àwọn obinrin kan láàrin wa sọ ohun tí ó yà wá lẹ́nu. Wọ́n jí lọ sí ibojì,

23. wọn kò rí òkú rẹ̀. Wọ́n wá ń sọ pé àwọn rí àwọn angẹli tí wọ́n sọ pé ó ti wà láàyè.

24. Ni àwọn kan ninu wa bá lọ sí ibojì. Wọ́n bá gbogbo nǹkan bí àwọn obinrin ti wí, ṣugbọn wọn kò rí òun alára.”

25. Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ!

26. Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.”

27. Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.

28. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ abúlé tí wọn ń lọ, Jesu ṣe bí ẹni pé ó fẹ́ máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ.

29. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀ ẹ́ pupọ pé, “Dúró lọ́dọ̀ wa, ọjọ́ ti lọ, ilẹ̀ ti ṣú.” Ni ó bá bá wọn wọlé, ó dúró lọ́dọ̀ wọn.

30. Nígbà tí ó ń bá wọn jẹun, ó mú burẹdi, ó súre sí i, ó bù ú, ó bá fi fún wọn.

31. Ojú wọn bá là; wọ́n wá mọ̀ pé Jesu ni. Ó bá rá mọ́ wọn lójú.

32. Wọ́n wá ń bá ara wọn sọ pé, “Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú wa lọ́kàn bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà, ati bí ó ti ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ fún wa!”

33. Wọ́n bá dìde lẹsẹkẹsẹ, wọ́n pada lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla ati àwọn tí ó wà pẹlu wọn níbi tí wọ́n péjọ sí,

34. àwọn ni wọ́n wá sọ fún wọn pé, “Oluwa ti jí dìde nítòótọ́, ó ti fara han Simoni.”

35. Ni àwọn náà wá ròyìn ìrírí wọn ní ojú ọ̀nà ati bí wọ́n ti ṣe mọ̀ ọ́n nígbà tí ó bu burẹdi.

36. Bí wọ́n ti ń sọ àwọn nǹkan wọnyi lọ́wọ́, Jesu alára bá dúró láàrin wọn. Ó ní, “Alaafia fun yín.”

37. Wọ́n ta gìrì, ẹ̀rù bà wọ́n; wọ́n ṣebí iwin ni.

Ka pipe ipin Luku 24