Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 23:6-18 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí Pilatu gbọ́ èyí, ó bèèrè bí ará Galili bá ni Jesu.

7. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé lábẹ́ àṣẹ Hẹrọdu ni ó wà, ó rán an sí Hẹrọdu, nítorí pé Hẹrọdu náà kúkú wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.

8. Nígbà tí Hẹrọdu rí Jesu, inú rẹ̀ dùn pupọ. Nítorí ó ti pẹ́ tí ó ti fẹ́ rí i, nítorí ìró rẹ̀ tí ó ti ń gbọ́. Ó ń retí pé kí Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú òun.

9. Ó bi Jesu ní ọpọlọpọ ìbéèrè ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn rárá.

10. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin dúró níbẹ̀, wọ́n ń tẹnu mọ́ ẹ̀sùn tí wọn fi kàn án.

11. Hẹrọdu ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n gbé ẹ̀wù dáradára kan wọ̀ ọ́; Hẹrọdu bá tún fi ranṣẹ pada sí Pilatu.

12. Ní ọjọ́ náà Hẹrọdu ati Pilatu di ọ̀rẹ́ ara wọn; nítorí tẹ́lẹ̀ rí ọ̀tá ni wọ́n ń bá ara wọn ṣe.

13. Pilatu bá pe àwọn olórí alufaa, ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan jọ,

14. ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fa ọkunrin yìí wá sọ́dọ̀ mi bí ẹni tí ó ń ba ìlú jẹ́. Lójú yín ni mo wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, tí n kò sì rí àìdára kan tí ó ṣe, ninu gbogbo ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án.

15. Hẹrọdu náà kò rí nǹkankan wí sí i, nítorí ńṣe ni ó tún dá a pada sí wa. Ó dájú pé ọkunrin yìí kò ṣe nǹkankan tí ó fi yẹ kí á dá a lẹ́bi ikú.

16. Nítorí náà nígbà tí a bá ti nà án tán, n óo dá a sílẹ̀.” [

17. Nítorí ó níláti dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún wọn ní àkókò àjọ̀dún.]

18. Ṣugbọn gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé, “Mú eléyìí lọ! Baraba ni kí o dá sílẹ̀ fún wa.”

Ka pipe ipin Luku 23